Galatia 2:6
Galatians 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi.
Galatians 2:6 in English
Galatians 2:6 · Berean Standard Bible
But as for the highly esteemed—whatever they were makes no difference to me; God does not show favoritism *—those leaders added nothing to me.
Context
4Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. 5Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìyìnrere náà. 6Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. 7Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. 8Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.