Galatia 1:13
Galatians 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́.
Galatians 1:13 in English
Galatians 1:13 · Berean Standard Bible
For you have heard of my former way of life in Judaism, how severely I persecuted the church of God and tried to destroy it.
Context
11Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi. 13Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́. 14Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.