Esra 9:5
Ezra 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.
Ezra 9:5 in English
Ezra 9:5 · Berean Standard Bible
At the evening offering, I got up from my humiliation with my tunic and cloak torn, and I fell on my knees, spread out my hands to the LORD my God,
Context
3Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo tu irun orí àti irùngbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìjayà. 4Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́. 5Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi. 6Mo sì gbàdúrà:
“Ojú tì mí gidigidi, tí n kò fi lè gbé ojú mi sókè sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá di púpọ̀ ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ga kan àwọn ọ̀run. 7Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.