Esra 7:20
Ezra 7:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.
Ezra 7:20 in English
Ezra 7:20 · Berean Standard Bible
And if anything else is needed for the house of your God that you may have occasion to supply, you may pay for it from the royal treasury.
Context
18Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín. 19Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jerusalẹmu fún ìsìn nínú tẹmpili Ọlọ́run rẹ. 20Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba. 21Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín 22tó ọgọ́rùn-ún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òsùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.