Esra 6:11
Ezra 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.
Ezra 6:11 in English
Ezra 6:11 · Berean Standard Bible
I also decree that if any man interferes with this directive, a beam is to be torn from his house and raised up, and he is to be impaled on it. And his own house shall be made a pile of rubble for this offense.*
Context
9Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀. 10Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀. 11Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn. 12Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run.
Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà. 13Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.