Native Bible

Ezra 5:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”

Ezra 5:4 in English

Ezra 5:4 · Berean Standard Bible

They also asked,* “What are the names of the men who are constructing this building?”

Context

2Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́. 3Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” 4Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?” 5Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 6Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.