Esra 4:18
Ezra 4:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.
Ezra 4:18 in English
Ezra 4:18 · Berean Standard Bible
The letter you sent us has been translated and read in my presence.
Context
16A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbègbè Eufurate. 17Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà.
Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate.
Ìkíni. 18A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. 19Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsin yìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò. 20Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.