Native Bible

Ezra 4:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn aṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò rí i wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oníwàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.

Ezra 4:15 in English

Ezra 4:15 · Berean Standard Bible

that a search should be made of the record books of your fathers. In these books you will discover and verify that the city is a rebellious city, harmful to kings and provinces, inciting sedition from ancient times. That is why this city was destroyed.

Context

13Síwájú sí i, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù. 14Nísinsin yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba, 15kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn aṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò rí i wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oníwàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run. 16A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbègbè Eufurate. 17Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà. Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate. Ìkíni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.