Esra 3:2
Ezra 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run.
Ezra 3:2 in English
Ezra 3:2 · Berean Standard Bible
Then Jeshua son of Jozadak * and his fellow priests, along with Zerubbabel son of Shealtiel and his associates, began to build the altar of the God of Israel to sacrifice burnt offerings on it, as it is written in the Law of Moses the man of God.
Context
1Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jerusalẹmu. 2Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run. 3Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n síbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́. 4Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ẹbọ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.