Esra 3:12
Ezra 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀.
Ezra 3:12 in English
Ezra 3:12 · Berean Standard Bible
But many of the older priests, Levites, and family heads who had seen the first temple wept loudly when they saw the foundation of this temple. Still, many others shouted joyfully.
Context
10Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. 11Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa:
“Ó dára;
ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.”
Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀. 12Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. 13Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.