Native Bible

Ezra 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Esra yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jókòó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà,

Ezra 10:16 in English

Ezra 10:16 · Berean Standard Bible

So the exiles did as proposed. Ezra the priest selected men who were family heads, each of them identified by name, to represent their families. On the first day of the tenth month they launched the investigation,

Context

14Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ́ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa. 15Jonatani ọmọ Asaheli àti Jahseiah ọmọ Tikfa nìkan pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Meṣullamu àti Ṣabbetai ará Lefi, ni wọ́n tako àbá yìí. 16Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Esra yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jókòó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà, 17ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. 18Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ: Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.