Esra 1:2
Ezra 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.
Ezra 1:2 in English
Ezra 1:2 · Berean Standard Bible
“This is what Cyrus king of Persia says: ‘The LORD, the God of heaven, who has given me all the kingdoms of the earth, has appointed me to build a house for Him at Jerusalem in Judah.
Context
1Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé, 2“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:
“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. 3Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. 4Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.