Esekiẹli 8:3
Ezekiel 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi.
Ezekiel 8:3 in English
Ezekiel 8:3 · Berean Standard Bible
He stretched out what looked like a hand and took me by the hair of my head. Then the Spirit lifted me up between earth and heaven and carried me in visions of God to Jerusalem, to the entrance of the north gate of the inner court, where the idol that provokes jealousy was seated.
Context
1Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Juda níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Olódùmarè bà lé mi níbẹ̀. 2Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí ó jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà. 3Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi. 4Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀. 5Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.