Esekiẹli 6:3
Ezekiel 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run.
Ezekiel 6:3 in English
Ezekiel 6:3 · Berean Standard Bible
You are to say: ‘O mountains of Israel, hear the word of the Lord GOD! This is what the Lord GOD says to the mountains and hills, to the ravines and valleys: I am about to bring a sword against you, and I will destroy your high places.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé, 2“Ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn òkè Israẹli; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn 3wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run. 4Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn. 5Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.