Esekiẹli 48:3
Ezekiel 48:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
Ezekiel 48:3 in English
Ezekiel 48:3 · Berean Standard Bible
Naphtali will have one portion bordering the territory of Asher from east to west.
Context
1“Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn:
“Ní òpin àríwá, Dani yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hetiloni lọ sí Lebo-Hamati; Hasari-Enani àti ààlà àríwá tí Damasku tí ó kángun sí Hamati yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn. 2Aṣeri yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbègbè Dani láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 3Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 4Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn. 5Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.