Esekiẹli 48:23
Ezekiel 48:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ti àwọn ẹ̀yà tí ó kù: “Benjamini yóò ní ìpín kan; èyí yóò wà láti ìhà ìlà-oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀-oòrùn.
Ezekiel 48:23 in English
Ezekiel 48:23 · Berean Standard Bible
As for the rest of the tribes: Benjamin will have one portion extending from the east side to the west side.
Context
21“Èyí tí ó ṣẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbègbè tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Èyí yóò lọ títí dé ìhà ìlà-oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà-oòrùn. Agbègbè méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹmpili yóò wa ní àárín wọn. 22Ilẹ̀ ìní àwọn Lefi àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárín agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé yóò wà ní àárín ààlà tí Juda àti ààlà tí Benjamini. 23“Ní ti àwọn ẹ̀yà tí ó kù:
“Benjamini yóò ní ìpín kan; èyí yóò wà láti ìhà ìlà-oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀-oòrùn. 24Simeoni yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Benjamini láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 25Isakari yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Simeoni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.