Esekiẹli 48:19
Ezekiel 48:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dá oko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Ezekiel 48:19 in English
Ezekiel 48:19 · Berean Standard Bible
The workers of the city who cultivate it will come from all the tribes of Israel.
Context
17Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. 18Èyí tí ó kù ní agbègbè náà, tí ó jẹ́ àkọjúsí ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlú ńlá náà. 19Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dá oko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli. 20Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà. 21“Èyí tí ó ṣẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbègbè tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Èyí yóò lọ títí dé ìhà ìlà-oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà-oòrùn. Agbègbè méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹmpili yóò wa ní àárín wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.