Esekiẹli 47:14
Ezekiel 47:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.
Ezekiel 47:14 in English
Ezekiel 47:14 · Berean Standard Bible
You are to divide it equally among them. Because I swore with an uplifted hand to give it to your forefathers, this land will fall to you as an inheritance.
Context
12Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.” 13Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu. 14Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín. 15“Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà:
“Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi Òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hetiloni gbà tí Hamati lọ sí Sedadi, 16Berota àti Sibraimu, èyí tí ó wà ní ààlà láàrín Damasku àti Hamati títí dé Hasari Hatikonu, èyí tí ó wà ní agbègbè Haurani.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.