Native Bible

Ezekiel 47:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.

Ezekiel 47:11 in English

Ezekiel 47:11 · Berean Standard Bible

But the swamps and marshes will not become fresh; they will be left for salt.

Context

9Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. 10Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. 11Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. 12Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.” 13Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.