Native Bible

Ezekiel 46:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan.

Ezekiel 46:7 in English

Ezekiel 46:7 · Berean Standard Bible

He is to provide a grain offering of an ephah with the bull, an ephah with the ram, and as much as he is able with the lambs, along with a hin of oil per ephah.

Context

5Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. 6Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n. 7Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan. 8Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde. 9“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.