Native Bible

Ezekiel 46:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.

Ezekiel 46:4 in English

Ezekiel 46:4 · Berean Standard Bible

The burnt offering that the prince presents to the LORD on the Sabbath day shall be six unblemished male lambs and an unblemished ram.

Context

2Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́. 3Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. 4Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù. 5Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. 6Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.