Native Bible

Ezekiel 46:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ, tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ.

Ezekiel 46:16 in English

Ezekiel 46:16 · Berean Standard Bible

This is what the Lord GOD says: ‘If the prince gives a gift to any of his sons as an inheritance, it will belong to his descendants. It will become their property by inheritance.

Context

14Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. 15Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. 16“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ, tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ. 17Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀, lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn. 18Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.