Esekiẹli 45:24
Ezekiel 45:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.
Ezekiel 45:24 in English
Ezekiel 45:24 · Berean Standard Bible
He shall also provide as a grain offering an ephah for each bull and an ephah for each ram, along with a hin of olive oil for each ephah of grain.*
Context
22Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà. 23Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan. 25“ ‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.