Esekiẹli 45:21
Ezekiel 45:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.
Ezekiel 45:21 in English
Ezekiel 45:21 · Berean Standard Bible
On the fourteenth day of the first month you are to observe the Passover, a feast of seven days, during which unleavened bread shall be eaten.
Context
19Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú. 20Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run. 21“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà. 22Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà. 23Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.