Esekiẹli 44:15
Ezekiel 44:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.
Ezekiel 44:15 in English
Ezekiel 44:15 · Berean Standard Bible
But the Levitical priests, who are descended from Zadok and who kept charge of My sanctuary when the Israelites went astray from Me, are to approach Me to minister before Me. They will stand before Me to offer Me fat and blood, declares the Lord GOD.
Context
13Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ nǹkan kan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn. 14Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe níbẹ̀. 15“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí. 16Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi. 17“ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.