Esekiẹli 43:23
Ezekiel 43:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ.
Ezekiel 43:23 in English
Ezekiel 43:23 · Berean Standard Bible
When you have finished the purification, you are to present a young, unblemished bull and an unblemished ram from the flock.
Context
21Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a sàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́. 22“Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù. 23Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ. 24Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa, àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 25“Fún ọjọ́ méje, ìwọ ní láti pèsè akọ ewúrẹ́ kan lójoojúmọ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; ìwọ yóò sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò láti inú agbo, méjèèjì yóò sì jẹ́ aláìlábàwọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.