Native Bible

Ezekiel 42:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.

Ezekiel 42:9 in English

Ezekiel 42:9 · Berean Standard Bible

And below these chambers was the entrance on the east side as one enters them from the outer court.

Context

7Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fà á gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 8Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó súnmọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 9Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́. 10Ní ìhà gúúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà. 11Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.