Native Bible

Ezekiel 41:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Agbègbè tí ó wà lófo ní àárín àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo.

Ezekiel 41:9 in English

Ezekiel 41:9 · Berean Standard Bible

The outer wall of the side rooms was five cubits thick, and the open area between the side rooms of the temple

Context

7Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo tẹmpili ń fẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń lọ sí òkè sí i. Àwọn ilé tí a kọ́ yípo ilé Ọlọ́run ni a kọ́ sókè ní pele ní pele, èyí mú kí àwọn yàrá yìí máa fẹ̀ sí i bí ó ṣe ń gòkè sí i. Àtẹ̀gùn rẹ̀ gba ti àwùjọ ilé àárín lọ sókè láti ilé títí dé òkè pátápátá. 8Mo ri i pé ilé Ọlọ́run náà ní ìgbásẹ̀ tí a mọ yí i ká, tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ilé tí a mọ yí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ po. Ó jẹ́ ìwọ̀n ọ̀pá náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní gígùn. 9Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Agbègbè tí ó wà lófo ní àárín àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo. 10Yàrá àwọn àlùfáà jẹ́ ogun ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú yípo tẹmpili náà. 11Àwọn ojú ọ̀nà àbáwọlé wá sí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́, ọ̀kan ní àríwá àti èkejì ní gúúsù, ojú ọ̀nà ni ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú yípo rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.