Esekiẹli 41:4
Ezekiel 41:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́; o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́. O sì sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni Ibi Mímọ́ Jùlọ.”
Ezekiel 41:4 in English
Ezekiel 41:4 · Berean Standard Bible
Then he measured the room adjacent to the inner sanctuary * to be twenty cubits long and twenty cubits wide.* And he said to me, “This is the Most Holy Place.*”
Context
2Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú, ẹ̀gbẹ́ ògiri ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ó sì wọn ìta ibi mímọ́ bákan náà; ó jẹ́ ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. 3Lẹ́yìn náà ó lọ sí inú yàrá ibi mímọ́, ó sì wọn àtẹ́rígbà àbáwọlé, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni ìbú. Àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni ìbú, ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ni ìbú. 4O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́; o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́. O sì sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni Ibi Mímọ́ Jùlọ.” 5Lẹ́yìn náà ó wọn ògiri ilé Ọlọ́run náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní nínípọn, yàrá kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú. 6Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ wà ni ipele mẹ́ta, lórí ara wọn, nígbà ọgbọ̀n lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn òpó ẹlẹ́wà wà yípo ògiri ilé Ọlọ́run náà mú kí ògiri àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà ní agbára, ni ọ̀nà tí àwọn ìfaratì náà kò fi wọ inú ògiri ilé Ọlọ́run náà lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.