Esekiẹli 41:15
Ezekiel 41:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba,
Ezekiel 41:15 in English
Ezekiel 41:15 · Berean Standard Bible
Next he measured the length of the building facing the temple courtyard at the rear of the temple, including its galleries on each side; it was a hundred cubits. The outer sanctuary, the inner sanctuary, and the porticoes facing the court,
Context
13Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn. 14Ibú ìta gbangba ilé Ọlọ́run ní ìhà ìlà-oòrùn, papọ̀ mọ́ iwájú ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 15Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba, 16àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò. Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátápátá. 17Ní ìta gbangba lókè ìta ẹnu-ọ̀nà inú ibi mímọ́ àti lára ògiri pẹ̀lú àlàfo tí kò ju ara wọn lọ yípo inú ìta ibi mímọ́
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.