Esekiẹli 40:45
Ezekiel 40:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún mi pé, “Yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà.
Ezekiel 40:45 in English
Ezekiel 40:45 · Berean Standard Bible
Then the man said to me: “The chamber that faces south is for the priests who keep charge of the temple,
Context
43Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká. Àwọn tẹmpili náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ. 44Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹmpili. 45Ó sì wí fún mi pé, “Yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà. 46Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sadoku nínú àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.” 47Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.