Native Bible

Ezekiel 40:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn ẹnu-ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.

Ezekiel 40:32 in English

Ezekiel 40:32 · Berean Standard Bible

And he brought me to the inner court on the east side, and he measured the gateway; it had the same measurements as the others.

Context

30(Àwọn àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jíjìn). 31Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i. 32Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn ẹnu-ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 33Àwọn yàrá kéékèèké rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 34Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.