Esekiẹli 40:25
Ezekiel 40:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnu-ọ̀nà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú.
Ezekiel 40:25 in English
Ezekiel 40:25 · Berean Standard Bible
Both the gateway and its portico had windows all around, like the other windows. It was fifty cubits long and twenty-five cubits wide.
Context
23Ẹnu-ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni ìdojúkọ ẹnu-ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà-oòrùn. Ó wọ́n láti ẹnu-ọ̀nà sí ìdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 24Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúúsù, mo sì rí ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ gúúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù. 25Ẹnu-ọ̀nà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 26Àtẹ̀gùn méje ní ń bẹ láti bá gun òkè rẹ̀, àti àwọn ìloro rẹ̀ sì ń bẹ níwájú wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 27Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu-ọ̀nà yìí sí ẹnu-ọ̀nà ìta ni ìhà gúúsù; o jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.