Native Bible

Ezekiel 38:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali.

Ezekiel 38:3 in English

Ezekiel 38:3 · Berean Standard Bible

and declare that this is what the Lord GOD says: Behold, I am against you, O Gog, chief prince of Meshech and Tubal.*

Context

1Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i 3kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali. 4Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ-ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹṣinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèké, gbogbo wọn ń fi idà wọn. 5Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.