Native Bible

Ezekiel 38:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì sọ fún Gogu: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Israẹli ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?

Ezekiel 38:14 in English

Ezekiel 38:14 · Berean Standard Bible

Therefore prophesy, son of man, and tell Gog that this is what the Lord GOD says: On that day when My people Israel are dwelling securely, will you not take notice of this?*

Context

12Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.” 13Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’ ” 14“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì sọ fún Gogu: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Israẹli ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀? 15Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹṣin ẹgbẹ́ ńlá, jagunjagun alágbára. 16Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Israẹli ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gogu, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fi ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.