Esekiẹli 37:23
Ezekiel 37:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
Ezekiel 37:23 in English
Ezekiel 37:23 · Berean Standard Bible
They will no longer defile themselves with their idols or detestable images, or with any of their transgressions. I will save them from all their apostasies by which they sinned,* and I will cleanse them. Then they will be My people, and I will be their God.
Context
21kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn. 22Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì. 23Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 24“ ‘Dafidi ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́. 25Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.