Native Bible

Ezekiel 36:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn.

Ezekiel 36:30 in English

Ezekiel 36:30 · Berean Standard Bible

I will also make the fruit of the trees and the crops of the field plentiful, so that you will no longer bear reproach among the nations on account of famine.

Context

28Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 31Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.