Esekiẹli 35:14
Ezekiel 35:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro.
Ezekiel 35:14 in English
Ezekiel 35:14 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says: While the whole earth rejoices, I will make you desolate.
Context
12Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti gbọ́ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Israẹli náà. Ìwọ wí pé, “A sọ wọ́n di ahoro, a sì fi wọ́n fún wa láti run.” 13Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ. 14Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro. 15Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Israẹli di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Seiri, ìwọ àti gbogbo ará Edomu. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.