Native Bible

Ezekiel 34:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì ṣí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rùbà wọ́n.

Ezekiel 34:28 in English

Ezekiel 34:28 · Berean Standard Bible

They will no longer be prey for the nations, and the beasts of the earth will not consume them. They will dwell securely, and no one will frighten them.

Context

26Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà. 27Àwọn igi igbó yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A yóò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú. 28Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì ṣí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rùbà wọ́n. 29Èmi yóò pèsè ilẹ̀ ti o ní oríyìn fún èso rẹ̀ fún wọn, wọn kì yóò sì jìyà nípasẹ̀ ìyàn mọ́ ni ilẹ̀ náà tàbí ru ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè. 30Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, èmi wà pẹ̀lú wọn àti pé, àwọn ilé Israẹli jẹ́ ènìyàn mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.