Esekiẹli 34:2
Ezekiel 34:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, fi àsọtẹ́lẹ̀ tako Olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; sọtẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn Israẹli tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́-àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?
Ezekiel 34:2 in English
Ezekiel 34:2 · Berean Standard Bible
“Son of man, prophesy against the shepherds of Israel. Prophesy and tell them that this is what the Lord GOD says: ‘Woe to the shepherds of Israel, who only feed themselves! Should not the shepherds feed their flock?
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ mi wá: 2“Ọmọ ènìyàn, fi àsọtẹ́lẹ̀ tako Olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; sọtẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn Israẹli tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́-àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran? 3Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran. 4Ìwọ kò ì tí ì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tí ì mú aṣáko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.