Native Bible

Ezekiel 34:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?

Ezekiel 34:18 in English

Ezekiel 34:18 · Berean Standard Bible

Is it not enough for you to feed on the good pasture? Must you also trample the rest of the pasture with your feet? Is it not enough for you to drink the clear waters? Must you also muddy the rest with your feet?

Context

16Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fi ara pa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùṣọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo. 17“ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrín àgbò àti ewúrẹ́. 18Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín? 19Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀? 20“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún wọn: Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.