Esekiẹli 34:11
Ezekiel 34:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Nítorí èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn.
Ezekiel 34:11 in English
Ezekiel 34:11 · Berean Standard Bible
For this is what the Lord GOD says: ‘Behold, I Myself will search for My flock and seek them out.
Context
9nítorí náà, ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 10Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn Olùṣọ́-àgùntàn, èmi yóò sì béèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́. 11“ ‘Nítorí èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn. 12Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́nká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ni ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn. 13Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ̀ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Israẹli, ni àárín àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.