Native Bible

Ezekiel 33:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá.

Ezekiel 33:28 in English

Ezekiel 33:28 · Berean Standard Bible

I will make the land a desolate waste, and the pride of her strength will come to an end. The mountains of Israel will become desolate, so that no one will pass through.

Context

26Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yín ba á obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’ 27“Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìṣọ́ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò pa. 28Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá. 29Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe.’ 30“Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.