Native Bible

Ezekiel 31:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀.

Ezekiel 31:16 in English

Ezekiel 31:16 · Berean Standard Bible

I made the nations quake at the sound of its downfall, when I cast it down to Sheol with those who descend to the Pit. Then all the trees of Eden, the choicest and best of Lebanon, all the well-watered trees, were consoled in the earth below.

Context

14Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀. 15“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà, mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. 16Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. 17Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa. 18“ ‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. “ ‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.