Esekiẹli 30:24
Ezekiel 30:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa.
Ezekiel 30:24 in English
Ezekiel 30:24 · Berean Standard Bible
I will strengthen the arms of Babylon’s king and place My sword in his hand, but I will break the arms of Pharaoh, who will groan before him like a mortally wounded man.
Context
22Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀. 23Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀. 24Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa. 25Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti. 26Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.