Esekiẹli 29:17
Ezekiel 29:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
Ezekiel 29:17 in English
Ezekiel 29:17 · Berean Standard Bible
In the twenty-seventh year, on the first day of the first month, the word of the LORD came to me, saying,
Context
15Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ” 17Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18“Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.