Esekiẹli 29:12
Ezekiel 29:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.
Ezekiel 29:12 in English
Ezekiel 29:12 · Berean Standard Bible
I will make the land of Egypt a desolation among desolate lands, and her cities will lie desolate for forty years among the ruined cities. And I will disperse the Egyptians among the nations and scatter them throughout the countries.
Context
10nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀. 13“ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.