Esekiẹli 29:1
Ezekiel 29:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
Ezekiel 29:1 in English
Ezekiel 29:1 · Berean Standard Bible
In the tenth year, on the twelfth day of the tenth month, the word of the LORD came to me, saying,
Context
1Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ.
Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.