Native Bible

Ezekiel 27:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

Ezekiel 27:17 in English

Ezekiel 27:17 · Berean Standard Bible

Judah and the land of Israel traded with you; they exchanged wheat from Minnith, cakes and honey, oil and balm for your merchandise.

Context

15“ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ. 16“ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ. 17“ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ. 18“ ‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.