Esekiẹli 26:9
Ezekiel 26:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.
Ezekiel 26:9 in English
Ezekiel 26:9 · Berean Standard Bible
He will direct the blows of his battering rams against your walls and tear down your towers with his axes.
Context
7“Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun. 8Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ. 9Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀. 10Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá. 11Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.